2 Chronicles 24:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọ̀ ile Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, nwọn si nsìn òriṣa ati ere: ibinu si wá sori Juda ati Jerusalemu nitori ẹ̀ṣẹ wọn yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n pa ilé OLÚWA tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹbí wọn, ìbínu Ọlọ́run dé sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.