2 Chronicles 24:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ̀ Oluwa wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti wù kí ó rí, OLÚWA rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.