2 Chronicles 24:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ṣákáríhà ọmọ Jéhóíádà wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ OLÚWA? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ OLÚWA sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”