2 Chronicles 24:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joaṣi ọba kò ranti oore tí Jehoiada, baba Sakaraya ṣe fún un, ṣugbọn ó pa ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó sì ń kú lọ, ó ní, “Kí OLUWA wo ohun tí o ṣe yìí, kí ó sì gbẹ̀san.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Joaṣi, ọba, kò ranti õre ti Jehoiada, baba rẹ̀, ti ṣe fun u, o si pa ọmọ rẹ̀. Nigbati o si nkú lọ, o wipe, Ki Oluwa ki o wò o, ki o si bère rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Jóáṣì kò rántí inú rere tí Jéhóiádà baba Ṣakaráyà ti fi hàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí OLÚWA kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣírò.”