2 Chronicles 24:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ ogun Árámì yàn láti dojúkọ Jóáṣì; wọ́n gbógun ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa gbogbo àwọn asáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Dámásíkọ́sì.