2 Chronicles 24:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọmọ Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Árámù kúrò, wọ́n fi Jóásì sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn onísẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jéhóiádà àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba.