2 Chronicles 24:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ lọ́pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwe ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.