2 Chronicles 24:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi jọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, ki ẹ si gbà owo jọ lati ọwọ gbogbo Israeli, lati tun ile Ọlọrun nyin ṣe li ọdọdun, ki ẹ si mu ọ̀ran na yá kankan. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi kò mu ọ̀ran na yá kánkan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó pe Àwọn Àlùfáà àti àwọn ará Léfì jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Júdà, kí ẹ sì gba owó ìtọ̀sì lati ọwọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti fi tún ilé Ọlọ́run ṣe, ṣé nísinsìn yìí” Ṣùgbọ́n àwọn ará Léfì kò ṣe é lẹ́ẹ́kan naà.