2 Chronicles 24:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kede ni Juda ati Jerusalemu, lati mu owo ofin fun Oluwa wá, ti Mose iranṣẹ Ọlọrun, fi le Israeli lori li aginju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ṣe ìkéde ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún OLÚWA, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti bèèrè lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ní ihà.