2 Chronicles 25:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹgbãrun alãye li awọn ọmọ Juda kó ni igbekun lọ, nwọn si mu wọn lọ si òke apata na, nwọn si tãri wọn silẹ lati òke apata na, nwọn si fọ́ tũtu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.