2 Chronicles 25:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun ti Amasiah ran pada lọ, ki nwọn ki o máṣe ba on lọ si ogun, kọlù awọn ilu Juda lati Samaria titi de Bet-horoni, nwọn si pa ẹgbẹdogun ninu wọn, nwọn si kó ikógun pipọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.