2 Chronicles 25:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbínú OLÚWA ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”