2 Chronicles 25:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.” Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe bi o ti mba a sọ̀rọ, ọba si wi fun u pe, A ha fi ọ ṣe igbimọ̀ ọba bi? fi mọ: ẹ̃ṣe ti a o fi pa ọ? Nigbana ni woli na fi mọ; o si wipe, Emi mọ̀ pe, Ọlọrun ti pinnu rẹ̀ lati pa ọ run, nitoriti iwọ ti ṣe eyi, ti iwọ kò si tẹ eti si imọ̀ran mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgbà ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé OLÚWA ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tísí ìmọ̀ràn mi”
Recommended Reading