2 Chronicles 25:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joaṣi, ọba Israeli, si ranṣẹ si Amasiah, ọba Judah, wipe, Ẹgun-ọ̀gan ti o wà ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti o wà ni Lebanoni, wipe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ mi li aya: ẹranko igbẹ kan ti o wà ni Lebanoni si kọja nibẹ, o si tẹ ẹ̀gun-ọ̀gan na mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.