2 Chronicles 25:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ wipe, Kiyesi i, iwọ ti pa awọn ara Edomu; ọkàn rẹ si gbé soke lati ma ṣogo: njẹ gbe ile rẹ, ẽṣe ti iwọ nfiran fun ifarapa rẹ, ti iwọ o fi ṣubu, ani iwọ ati Juda pẹlu rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”