2 Chronicles 25:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì. Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù. Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn.