2 Chronicles 25:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ lẹhin àkoko ti Amasiah yipada kuro lati ma tọ̀ Oluwa lẹhin, nwọn di ọ̀tẹ si i ni Jerusalemu; o si salọ si Lakiṣi: ṣugbọn nwọn ranṣẹ tẹlẽ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà tí Ámásíà ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé OLÚWA, wọ́n dìtẹ̀ síi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákíṣì ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lákiṣì, wọ́n sì paá síbẹ̀.