2 Chronicles 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ámásíà, pe gbogbo àwọn ènìyàn Júdà pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọrọrún fún gbogbo Júdà àti Bẹńjámínì, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì ríi pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.