2 Chronicles 25:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn enia Ọlọrun kan tọ̀ ọ wá, wipe, Ọba, máṣe jẹ ki ogun Israeli ki o ba ọ lọ: nitoriti Oluwa kò wà pẹlu Israeli, ani gbogbo awọn ọmọ Efraimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí OLÚWA kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù.