2 Chronicles 25:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi iwọ o ba lọ, ma lọ, mu ara le fun ogun na: Ọlọrun yio bì ọ ṣubu niwaju ọta: Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ subú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí OLÚWA ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”