2 Chronicles 25:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?” Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ámásíà sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùnún tálẹ́ntì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́-ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́?” Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “OLÚWA lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.”