2 Chronicles 26:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ sinu aṣálẹ̀, ó gbẹ́ ọpọlọpọ kànga, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ agbo ẹran ọ̀sìn ní àwọn ẹsẹ̀ òkè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ń dá oko fún un ati àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu àjàrà, lórí òkè ati lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O kọ́ ile iṣọ li aginju pẹlu, o si wà kanga pupọ: nitoriti o li ẹran-ọsin pipọ, ati ni ilẹ isalẹ, ati ni pẹ̀tẹlẹ: o ni àgbẹ ati awọn olutọju àjara lori òke nla, ati lori Karmeli: nitoriti o fẹran àgbẹ-ṣiṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún ilé ìṣọ́ ihà kọ́, ó sì gbẹ́ kàǹga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbààjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.