2 Chronicles 26:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Usaya ní ọpọlọpọ ọmọ ogun, tí wọ́n tó ogun lọ, ó pín wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí ètò tí Jeieli akọ̀wé, ati Maaseaya, ọ̀gágun ṣe, lábẹ́ àkóso Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ussiah si li ẹgbẹ́-ogun awọn enia ti njagun, ti ima lọ ijagun li ẹgbẹgbẹ gẹgẹ bi iye kikà wọn, nipa ọwọ Jegieli, akọwe, ati Maaseiah, olori labẹ ọwọ Hananiah, ọkan ninu awọn olori ogun ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Úsíà sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jégíélì akọ̀wé àti Máséía ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hánánì, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun.