2 Chronicles 26:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lábẹ́ wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbaarin ati ẹẹdẹgbaata (307,500), wọ́n lágbára láti jagun, ati láti bá ọba dojú kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọwọ wọn li agbara ogun kan wà, ọkẹ mẹdogun enia o le ẹ̃dẹgbãrin ti o mura, ti nfi àgbara nla jagun, lati ràn ọba lọwọ si ọta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dogún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀.