2 Chronicles 26:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní àwọn ẹ̀rọ tí àwọn alágbẹ̀dẹ ṣe sórí àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn igun odi ní Jerusalẹmu láti máa tafà ati láti máa sọ àwọn òkúta ńláńlá. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri nítorí pé Ọlọrun ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nà ìyanu títí ó fi di alágbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ohun ẹrọ-ijagun ni Jerusalemu, ihumọ ọlọgbọ́n enia, lati wà lori ile-iṣọ, ati lori igun odi, lati fi tafa, ati lati fi sọ okuta nla. Orukọ rẹ̀ si tàn lọ jìnajina, nitoriti a ṣe iranlọwọ iyanu fun u, titi o fi li agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní Jérúsálẹ́mù ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun tí ó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ihumọ̀ ọlọgbọ́n ọkùnrin fún lílò lórí ilé-ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.