2 Chronicles 26:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dojú kọ ọ́, wọ́n ní, “Usaya, kò tọ́ fún ọ láti sun turari sí OLUWA; iṣẹ́ àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni ni, àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ láti máa sun turari. Jáde kúrò ninu ibi mímọ́! Nítorí o ti ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì buyì kún ọ lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si tako Ussiah ọba, nwọn si wi fun u pe, Ki iṣe tirẹ, Ussiah, lati sun turari fun Oluwa, bikòṣe ti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ti a yà si mimọ́ lati sun turari: jade kuro ni ibi mimọ́; nitoriti iwọ ti dẹṣẹ; bẹ̃ni kì yio ṣe fun ọlá rẹ lati ọdọ Oluwa Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì takòó, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ùsáyà, láti sun tùràrí sí OLÚWA. Èyi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìsòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run.”