2 Chronicles 26:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú bí Usaya nítorí pé àwo turari ti wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó fẹ́ fi sun turari. Níbi tí ó ti ń bínú sí àwọn alufaa, àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, lójú àwọn alufaa ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Ussiah binu, awo-turari si mbẹ lọwọ rẹ̀ lati sun turari: ati nigbati o binu si awọn alufa, ẹ̀tẹ yọ ni iwaju rẹ̀, loju awọn alufa ni ile Oluwa lẹba pẹpẹ turari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ùsía, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣe tán láti sun tùràrí, ó sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé OLÚWA, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀.