2 Chronicles 26:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Asaraya, olórí alufaa ati àwọn alufaa rí i tí ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, wọ́n yára tì í jáde. Ìkánjú ni òun pàápàá tilẹ̀ bá jáde, nítorí pé OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Asariah, olori alufa, ati gbogbo awọn alufa wò o, si kiyesi i, o dẹtẹ ni iwaju rẹ̀, nwọn si tì i jade kuro nibẹ, nitõtọ, on tikararẹ̀ yara pẹlu lati jade, nitoriti Oluwa ti lù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ásáríyà olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì ríi wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lú pẹ̀lú, òun tìkálárarẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí OLÚWA ti lùú.