2 Chronicles 26:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Usaya ọba di adẹ́tẹ̀ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́ ilé fún un tí ó ń dá gbé; nítorí wọ́n yọ ọ́ kúrò ninu ilé OLUWA. Jotamu ọmọ rẹ̀ di alákòóso ìjọba, ó sì ń darí àwọn ará ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ussiah ọba, si di adẹ̀tẹ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile àrun, nitori adẹtẹ ni iṣe, nitoriti a ké e kuro ninu ile Oluwa: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si wà lori ile ọba, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ùsíá sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé ọ̀tọ̀ adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ile OLÚWA. Jótamù ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.