2 Chronicles 26:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wá Ọlọrun li ọjọ Sekariah, ẹniti o li oye ninu iran Ọlọrun: niwọn ọjọ ti o wá Oluwa, Ọlọrun si mu u ṣe rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wá OLÚWA ní ọjọ́ Sekaríà, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ̀n ọjọ́ tí ó wá ojú OLÚWA, Ọlọ́run fún-un ní ohun rere.