2 Chronicles 27:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ẸNI ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jotamu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jótámù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógun. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jérúsà ọmọbìnrin Sádókì.