2 Chronicles 27:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe; kiki kò wọ inu tempili Oluwa lọ, ṣugbọn awọn enia nṣe ibi sibẹsibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé OLÚWA. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń se iṣẹ́ ibi wọn.