2 Chronicles 27:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jótanì sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ámónì ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ámórì wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà àti ẹgbàaàrún òsùwọ̀n àlìkámà àti ẹgbàárún balì. Àwọn ará Ámónì gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.