2 Chronicles 28:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ìgbèkùn wọnyi wọ ibí wá, kí ẹ tún wá dákún ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi tí ó wà lọ́rùn wa tẹ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ tẹ́lẹ̀, ọwọ́ ibinu OLUWA sì ti wà lára Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ mu awọn igbekun nì wá ihin: nitori wò o, awa ti jẹbi niwaju Oluwa, ẹnyin npete ati fi kún ẹ̀ṣẹ ati ẹbi wa: ẹbi wa sa tobi, ibinu kikan si wà lori Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” wọ́n wí pé, “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú OLÚWA, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi pupọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Ísírẹ́lì.”