2 Chronicles 28:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun náà dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú ati ẹrù tí wọn ń kó bọ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè ati gbogbo ìjọ eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awọn enia ti o hamọra fi awọn igbekun ati ikogun na silẹ niwaju awọn ijoye, ati gbogbo ijọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógún sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn.