2 Chronicles 28:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà. Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn.