2 Chronicles 28:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tilgati-pilnesari, ọba Assiria, si tọ̀ ọ wá, ọ si pọn ọ loju, ṣugbọn kò fun u li agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tílgátì-Pílésárì ọba Ásíríà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.