2 Chronicles 28:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó rúbọ sí àwọn oriṣa àwọn ará Damasku tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn oriṣa àwọn ọba Siria ràn wọ́n lọ́wọ́, n óo rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ran èmi náà lọ́wọ́.” Ṣugbọn àwọn oriṣa ọ̀hún ni wọ́n fa ìparun bá òun ati orílẹ̀-èdè rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti o rubọ si awọn oriṣa Damasku, awọn ẹniti o kọlù u: o si wipe, Nitoriti awọn oriṣa awọn ọba Siria ràn wọn lọwọ, nitorina li emi o rubọ si wọn, ki nwọn le ràn mi lọwọ. Ṣugbọn awọn na ni iparun rẹ̀ ati ti gbogbo Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Dámásíkù, ẹni tí ó sẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn síríà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì.