2 Chronicles 28:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ohun èlò ilé Ọlọrun ni Ahasi gé wẹ́wẹ́, ó sì ti ìlẹ̀kùn ibẹ̀; ó wá tẹ́ pẹpẹ oriṣa káàkiri Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasi si kó gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun jọ, o si ké kuro lara ohun-elo ile Ọlọrun, o si tì ilẹkun ile Oluwa, o si tẹ́ pẹpẹ fun ara rẹ̀ ni gbogbo igun Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhásì sì kó jọ gbogbo ohun èlò lati ilé OLÚWA jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ilẹ̀kùn ilé OLÚWA ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jérúsálẹ́mù.