2 Chronicles 28:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Ahasi ọba kú, wọ́n sin ín sí Jerusalẹmu, wọn kò sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba. Hesekaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu na, ani ni Jerusalemu; ṣugbọn nwọn kò mu u wá sinu awọn isa-okú awọn ọba Israeli: Hesekiah ọmọ rẹ si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn Baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jérúsálẹ́mù ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn ìsà òkú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Heṣekáyà ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.