2 Chronicles 28:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku. A si fi i le ọba Israeli lọwọ pẹlu, ti o pa a ni ipakupa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Síríà lọ́wọ́. Àwọn ará Síríà sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Dámásíkù. Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbékùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.