2 Chronicles 28:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ará ilẹ̀ Israẹli dè ní ìgbèkùn lọ ninu àwọn ará ilé Juda jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àtàwọn obinrin, àtàwọn ọmọkunrin, àtàwọn ọmọbinrin; wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun lọ sí Samaria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si kó ọkẹ mẹwa ninu awọn arakunrin wọn ni igbekun lọ, awọn obinrin, awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin, nwọn si kó ikogun pupọ lọdọ wọn pẹlu, nwọn si mu ikogun na wá si Samaria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kó ní ìgbékùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (2,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Saáríà.