2 Chronicles 28:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wòlíì OLÚWA tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Saáríà. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí OLÚWA, Ọlọ́run Baba yín bínú sí Júdà ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run.