2 Chronicles 29:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá kó àwọn arakunrin wọn jọ, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Wọ́n wọ ilé OLUWA láti tọ́jú rẹ̀ bí ọba ti pa á láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si wá nipa aṣẹ ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, lati gbá ile Oluwa mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nigbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ile OLÚWA mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti paáláṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLÚWA.