2 Chronicles 29:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa wọ ibi mímọ́ lọ láti tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun aláìmọ́ tí wọ́n rí ninu tẹmpili OLUWA ni wọ́n kó sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ọmọ Lefi sì kó gbogbo wọn lọ dà sí odò Kidironi lẹ́yìn ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfaà sì wọ inú ilé OLÚWA lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé OLÚWA gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé OLÚWA. Àwọn ọmọ Léfì sì mú u wọ́n sì gbé e jáde sí gbangba odò Kédírónì.