2 Chronicles 29:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nwọn bẹ̀rẹ li ọjọ kini oṣù kini, lati yà a si mimọ́, ati li ọjọ kẹjọ oṣù na, nwọn de iloro Oluwa: bẹ̃ni nwọn fi ọjọ mẹjọ yà ile Oluwa si mimọ́; ati li ọjọ kẹrindilogun oṣù kini na, nwọn pari rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyà sí mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro OLÚWA. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn síi, wọ́n sì ya ilé OLÚWA sí mímọ́ fún rarẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹ́rìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.