2 Chronicles 29:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ti pèsè àsì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Áhásì ti sọ di aláìmọ́ nínú àìsòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsìn yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ OLÚWA.”