2 Chronicles 29:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà. Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ OLÚWA.