2 Chronicles 29:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ: Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.