2 Chronicles 29:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hésékíà sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí OLÚWA bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì.